Saamu 18:14
Psalms 18:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
Psalms 18:14 in English
Psalms 18:14 · Berean Standard Bible
He shot His arrows and scattered the foes; He hurled lightning and routed them.
Context
12Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ
pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná 13Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;
Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná. 14Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,
ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú. 15A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn,
a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé
nípa ìbáwí rẹ, Olúwa,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ. 16Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;
Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.