Native Bible

Psalms 17:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.

Psalms 17:13 in English

Psalms 17:13 · Berean Standard Bible

Arise, O LORD, confront them! Bring them to their knees; deliver me from the wicked by Your sword,

Context

11Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká, pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀. 12Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ, àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀. 13Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ. 14Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí. Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn. 15Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.