Saamu 144:4
Psalms 144:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ènìyàn rí bí èmi; ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.
Psalms 144:4 in English
Psalms 144:4 · Berean Standard Bible
Man is like a breath; his days are like a passing shadow.
Context
2Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi. 3Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀? 4Ènìyàn rí bí èmi;
ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ. 5Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín. 6Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.