Native Bible

Psalms 143:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò.

Psalms 143:7 in English

Psalms 143:7 · Berean Standard Bible

Answer me quickly, O LORD; my spirit fails. Do not hide Your face from me, or I will be like those who descend to the Pit.

Context

5Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe. 6Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela. 7Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò. 8Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀: nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ. 9Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa, nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.