Saamu 141:3
Psalms 141:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa: kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
Psalms 141:3 in English
Psalms 141:3 · Berean Standard Bible
Set a guard, O LORD, over my mouth; keep watch at the door of my lips.
Context
1Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi.
Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́. 2Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí
àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́. 3Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:
kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́. 4Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,
láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú
má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn. 5Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́:
jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi.
Tí kì yóò fọ́ mi ní orí.
Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.