Native Bible

Psalms 140:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

Psalms 140:6 in English

Psalms 140:6 · Berean Standard Bible

I say to the LORD, “You are my God.” Hear, O LORD, my cry for help.

Context

4Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú; yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú. 5Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn: wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà; wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi. 6Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. 7Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà. 8Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un; má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́; kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.