Saamu 139:17
Psalms 139:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó!
Psalms 139:17 in English
Psalms 139:17 · Berean Standard Bible
How precious to me are Your thoughts,* O God, how vast is their sum!
Context
15Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, 16ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé,
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí. 17Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó! 18Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀. 19Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.