Native Bible

Psalms 125:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo; kí àwọn olódodo kí ó máa ba à fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

Psalms 125:3 in English

Psalms 125:3 · Berean Standard Bible

For the scepter of the wicked will not rest upon the land allotted to the righteous, so that the righteous will not put forth their hands to injustice.

Context

1Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni, tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé. 2Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. 3Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo; kí àwọn olódodo kí ó máa ba à fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀. 4Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere, àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin. 5Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.