Native Bible

Psalms 119:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

Psalms 119:2 in English

Psalms 119:2 · Berean Standard Bible

Blessed are those who keep His testimonies and seek Him with all their heart.

Context

1Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa. 2Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. 3Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 4Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.