Native Bible

Psalms 110:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ti búra, kò sì í yí ọkàn padà pé, “Ìwọ ni àlùfáà, ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

Psalms 110:4 in English

Psalms 110:4 · Berean Standard Bible

The LORD has sworn and will not change His mind: “You are a priest forever in the order of Melchizedek.”*

Context

2Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀ láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ. 3Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ. 4Olúwa ti búra, kò sì í yí ọkàn padà pé, “Ìwọ ni àlùfáà, ní ipasẹ̀ Melkisedeki.” 5Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀. 6Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí, yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara; yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.