Native Bible

Psalms 109:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀: bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.

Psalms 109:17 in English

Psalms 109:17 · Berean Standard Bible

The cursing that he loved, may it fall on him; the blessing in which he refused to delight, may it be far from him.

Context

15Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀. 16Nítorí kò rántí láti ṣàánú, ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú, kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn. 17Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀: bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí. 18Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi. 19Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.