Saamu 106:45
Psalms 106:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
Psalms 106:45 in English
Psalms 106:45 · Berean Standard Bible
And He remembered His covenant with them, and relented by the abundance of His loving devotion.
Context
43Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 44Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn, 45ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn. 46Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
ó mú wọn rí àánú. 47Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.