Òwe 5:20
Proverbs 5:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà, tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
Proverbs 5:20 in English
Proverbs 5:20 · Berean Standard Bible
Why be captivated, my son, by an adulteress, or embrace the bosom of a stranger?*
Context
18Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;
kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ. 19Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,
jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,
kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà. 20Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,
tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn? 21Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa
Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò. 22Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;
okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.