Òwe 4:25
Proverbs 4:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.
Proverbs 4:25 in English
Proverbs 4:25 · Berean Standard Bible
Let your eyes look forward; fix your gaze straight ahead.
Context
23Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́,
nítorí òun ni orísun ìyè. 24Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;
sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ. 25Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú,
jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á. 26Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ
sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan. 27Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;
pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.