Òwe 28:3
Proverbs 28:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ.
Proverbs 28:3 in English
Proverbs 28:3 · Berean Standard Bible
A destitute leader who oppresses the poor is like a driving rain that leaves no food.
Context
1Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e
ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún. 2Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀,
ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́. 3Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára
dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ. 4Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú
ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú. 5Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi
ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.