Òwe 27:8
Proverbs 27:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.
Proverbs 27:8 in English
Proverbs 27:8 · Berean Standard Bible
Like a bird that strays from its nest is a man who wanders from his home.
Context
6Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,
ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn. 7Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó
ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa. 8Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀
ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀. 9Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn
bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso. 10Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,
má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ
ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.