Òwe 24:23
Proverbs 24:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n: láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá.
Proverbs 24:23 in English
Proverbs 24:23 · Berean Standard Bible
These also are sayings of the wise: To show partiality in judgment is not good.
Context
21Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,
má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun. 22Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,
ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá? 23Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:
láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá. 24Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,”
àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́. 25Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,
ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.