Òwe 23:21
Proverbs 23:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.
Proverbs 23:21 in English
Proverbs 23:21 · Berean Standard Bible
For the drunkard and the glutton will come to poverty, and drowsiness will clothe them in rags.
Context
19Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,
kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́. 20Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;
àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun; 21nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà;
ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ. 22Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,
má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó. 23Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;
ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.