Òwe 21:12
Proverbs 21:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.
Proverbs 21:12 in English
Proverbs 21:12 · Berean Standard Bible
The Righteous One * considers the house of the wicked and brings the wicked to ruin.
Context
10Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi
aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 11Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn,
òpè a máa kọ́gbọ́n,
nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀. 12Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú
ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun. 13Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,
òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;
ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́. 14Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:
àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,
dẹ́kun ìbínú líle.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.