Native Bible

Proverbs 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn, ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.

Proverbs 20:17 in English

Proverbs 20:17 · Berean Standard Bible

Food gained by fraud is sweet to a man, but later his mouth is full of gravel.

Context

15Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ, ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye. 16Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn. 17Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn, ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀. 18Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà. 19Olófòófó a máa tú àṣírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.