Òwe 19:26
Proverbs 19:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.
Proverbs 19:26 in English
Proverbs 19:26 · Berean Standard Bible
He who assaults his father or evicts his mother is a son who brings shame and disgrace.
Context
24Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;
kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀. 25Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n;
bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i. 26Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde
òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá. 27Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́,
tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀. 28Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín,
ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.