Òwe 18:13
Proverbs 18:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́, èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
Proverbs 18:13 in English
Proverbs 18:13 · Berean Standard Bible
He who answers a matter before he hears it— this is folly and disgrace to him.
Context
11Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;
wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni. 12Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,
ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá. 13Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,
èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀. 14Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn,
ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì. 15Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;
etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.