Òwe 15:5
Proverbs 15:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
Proverbs 15:5 in English
Proverbs 15:5 · Berean Standard Bible
A fool rejects his father’s discipline, but whoever heeds correction is prudent.
Context
3Ojú Olúwa wà níbi gbogbo,
Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere. 4Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè
ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run. 5Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 6Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,
ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn. 7Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;
ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.