Òwe 14:30
Proverbs 14:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara, ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
Proverbs 14:30 in English
Proverbs 14:30 · Berean Standard Bible
A tranquil heart is life to the body, but envy rots the bones.
Context
28Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,
ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun. 29Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,
ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn. 30Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,
ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà. 31Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn
ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run. 32Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,
kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.