Native Bible

Proverbs 14:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.

Proverbs 14:16 in English

Proverbs 14:16 · Berean Standard Bible

A wise man fears * and turns from evil, but a fool is careless and reckless.

Context

14A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀. 15Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. 16Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra. 17Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè, a sì kórìíra eléte ènìyàn. 18Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.