Òwe 12:9
Proverbs 12:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.
Proverbs 12:9 in English
Proverbs 12:9 · Berean Standard Bible
Better to be lightly esteemed yet have a servant, than to be self-important but lack food.
Context
7A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;
ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin. 8A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀
ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn. 9Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́
ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ. 10Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,
ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni. 11Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.