Native Bible

Proverbs 11:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́.

Proverbs 11:13 in English

Proverbs 11:13 · Berean Standard Bible

A gossip reveals a secret, but a trustworthy person keeps a confidence.

Context

11Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run. 12Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́. 13Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́. 14Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú. 15Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.