Òwe 10:7
Proverbs 10:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún, ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.
Proverbs 10:7 in English
Proverbs 10:7 · Berean Standard Bible
The memory of the righteous is a blessing, but the name of the wicked will rot.
Context
5Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ. 6Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo,
ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú. 7Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún,
ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà. 8Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,
ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun. 9Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu,
ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.