Òwe 10:3
Proverbs 10:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo, ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
Proverbs 10:3 in English
Proverbs 10:3 · Berean Standard Bible
The LORD does not let the righteous go hungry, but He denies the craving of the wicked.
Context
1Àwọn òwe Solomoni.
Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn,
ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́. 2Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè,
ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. 3Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo,
ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́. 4Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà,
ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀. 5Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.