Òwe 10:19
Proverbs 10:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
Proverbs 10:19 in English
Proverbs 10:19 · Berean Standard Bible
When words are many, sin is unavoidable, but he who restrains his lips is wise.
Context
17Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà. 18Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́
ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n. 19Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù
ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà,
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí. 21Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.