Native Bible

Philippians 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀,

Philippians 3:4 in English

Philippians 3:4 · Berean Standard Bible

though I myself could have such confidence. If anyone else thinks he has grounds for confidence in the flesh, I have more:

Context

2Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà. 3Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara. 4Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀, 5ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi; 6ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.