Filipi 2:18
Philippians 2:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.
Philippians 2:18 in English
Philippians 2:18 · Berean Standard Bible
So you too should be glad and rejoice with me.
Context
16Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán. 17Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. 18Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú. 19Mo ni ìrètí nínú Jesu Olúwa, láti rán Timotiu sí yín ni àìpẹ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ni ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí mo bá gbúròó yín. 20Nítorí èmi kò ni ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyàn yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.