Native Bible

Numbers 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

Numbers 8:7 in English

Numbers 8:7 · Berean Standard Bible

This is what you must do to cleanse them: Sprinkle them with the water of purification. Have them shave their whole bodies and wash their clothes, and so purify themselves.

Context

5Olúwa sọ fún Mose pé, 6“Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́. 7Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. 8Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 9Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Israẹli jọ síbẹ̀ pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.