Numeri 8:6
Numbers 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.
Numbers 8:6 in English
Numbers 8:6 · Berean Standard Bible
“Take the Levites from among the Israelites and make them ceremonially clean.
Context
4Bí a ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyìí, a ṣe é láti ara wúrà lílù: láti ìsàlẹ̀ títí dé ibi ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí bátànì tí Olúwa fihan Mose. 5Olúwa sọ fún Mose pé, 6“Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́. 7Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. 8Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.