Numeri 7:85
Numbers 7:85 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin. Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá (2,400) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.
Numbers 7:85 in English
Numbers 7:85 · Berean Standard Bible
Each silver platter weighed a hundred and thirty shekels, and each silver bowl seventy shekels. The total weight of the silver articles was two thousand four hundred shekels,* according to the sanctuary shekel.
Context
83màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.
Èyí ni ọrẹ Ahira ọmọ Enani. 84Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí:
àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá. 85Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin. Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá (2,400) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. 86Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwo wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì. 87Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, àgbò méjìlá, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.