Native Bible

Numbers 7:84 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá.

Numbers 7:84 in English

Numbers 7:84 · Berean Standard Bible

So these were the offerings from the leaders of Israel for the dedication of the altar when it was anointed: twelve silver platters, twelve silver bowls, and twelve gold dishes.

Context

82akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; 83màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ahira ọmọ Enani. 84Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá. 85Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin. Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá (2,400) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. 86Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwo wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.