Numeri 6:14
Numbers 6:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà,
Numbers 6:14 in English
Numbers 6:14 · Berean Standard Bible
and he is to present an offering to the LORD of an unblemished year-old male lamb as a burnt offering, an unblemished year-old female lamb as a sin offering, and an unblemished ram as a peace offering—
Context
12Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀. 13“ ‘Èyí ni òfin fún Nasiri nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 14Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà, 15pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí. 16“ ‘Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá síwájú Olúwa, yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.