Native Bible

Numbers 4:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí.

Numbers 4:13 in English

Numbers 4:13 · Berean Standard Bible

Then they shall remove the ashes from the bronze altar, spread a purple cloth over it,

Context

11“Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. 12“Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù. 13“Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí. 14Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwokòtò. Kí wọn ó fi awọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. 15“Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.