Native Bible

Numbers 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

Numbers 4:11 in English

Numbers 4:11 · Berean Standard Bible

Over the gold altar they are to spread a blue cloth, cover it with fine leather, and insert the poles.

Context

9“Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 10Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e. 11“Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. 12“Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù. 13“Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.