Numeri 35:26
Numbers 35:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí.
Numbers 35:26 in English
Numbers 35:26 · Berean Standard Bible
But if the manslayer ever goes outside the limits of the city of refuge to which he fled
Context
24Àwọn àpéjọ gbọdọ̀ dájọ́ láàrín rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25Àpéjọ gbọdọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì rán an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbọdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi àmì òróró yàn. 26“ ‘Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí. 27Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láìjẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn. 28Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.