Native Bible

Numbers 35:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àpéjọ gbọdọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì rán an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbọdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi àmì òróró yàn.

Numbers 35:25 in English

Numbers 35:25 · Berean Standard Bible

The assembly is to protect the manslayer from the hand of the avenger of blood. Then the assembly will return him to the city of refuge to which he fled, and he must live there until the death of the high priest, who was anointed with the holy oil.

Context

23tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀tá rẹ̀, láti ṣe é léṣe. 24Àwọn àpéjọ gbọdọ̀ dájọ́ láàrín rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25Àpéjọ gbọdọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì rán an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbọdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi àmì òróró yàn. 26“ ‘Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí. 27Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láìjẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.