Numeri 32:31
Numbers 32:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Gadi àti ọmọ Reubeni dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí Olúwa ti sọ.
Numbers 32:31 in English
Numbers 32:31 · Berean Standard Bible
The Gadites and Reubenites replied, “As the LORD has spoken to your servants, so we will do.
Context
29Mose sì wí fún wọn pé, “Tí àwọn ọmọ Gadi àti ọmọ Reubeni, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra fún ogun rékọjá odò Jordani pẹ̀lú níwájú Olúwa, nígbà tí ẹ ṣẹ́gun ilẹ̀ náà níwájú yín, fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. 30Ṣùgbọ́n tí wọn kò bá fẹ́ bá yín rékọjá pẹ̀lú ìhámọ́ra, wọn gbọdọ̀ gba ìní wọn pẹ̀lú yín ní Kenaani.” 31Àwọn ọmọ Gadi àti ọmọ Reubeni dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí Olúwa ti sọ. 32A máa rékọjá níwájú Olúwa lọ sí Kenaani pẹ̀lú ìhámọ́ra, ṣùgbọ́n ẹrù tí a jogún yóò wà ní ẹ̀bá Jordani.” 33Nígbà náà Mose fún àwọn ọmọ Gadi àti àwọn ọmọ Reubeni àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu ní ilẹ̀ ọba Sihoni ọba àwọn ọmọ Amori àti ilẹ̀ ọba Ogu ọba Baṣani ní gbogbo ilẹ̀ náà pẹ̀lú ìlú rẹ̀ àti agbègbè tí ó yí i ka.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.