Numeri 32:27
Numbers 32:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra ogun, yóò rékọjá lọ láti jà níwájú Olúwa; gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti sọ.”
Numbers 32:27 in English
Numbers 32:27 · Berean Standard Bible
But your servants are equipped for war, and every man will cross over to the battle before the LORD, just as our lord says.”
Context
25Àwọn ọmọ Gadi àti ọmọ Reubeni sọ fún Mose pé, “Àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti pàṣẹ. 26Àwọn ọmọ wa àti ìyàwó wa, àwọn agbo ẹran àti ohun ọ̀sìn wa yóò dúró ní ìlú Gileadi. 27Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra ogun, yóò rékọjá lọ láti jà níwájú Olúwa; gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti sọ.” 28Nígbà náà ni Mose pàṣẹ nípa wọn fún Eleasari àlùfáà àti Joṣua ọmọ Nuni àti sí gbogbo olórí ìdílé ẹ̀yà Israẹli. 29Mose sì wí fún wọn pé, “Tí àwọn ọmọ Gadi àti ọmọ Reubeni, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra fún ogun rékọjá odò Jordani pẹ̀lú níwájú Olúwa, nígbà tí ẹ ṣẹ́gun ilẹ̀ náà níwájú yín, fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.