Native Bible

Numbers 31:53 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀.

Numbers 31:53 in English

Numbers 31:53 · Berean Standard Bible

Each of the soldiers had taken plunder for himself.

Context

51Mose àti Eleasari àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́. 52Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mose àti Eleasari, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì. 53Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀. 54Mose àti Eleasari àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú àgọ́ ìpàdé fún ìrántí àwọn Israẹli níwájú Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.