Numeri 28:9
Numbers 28:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò.
Numbers 28:9 in English
Numbers 28:9 · Berean Standard Bible
On the Sabbath day, present two unblemished year-old male lambs, accompanied by a grain offering of two-tenths of an ephah of fine flour * mixed with oil, as well as a drink offering.
Context
7Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́. 8Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ́júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn sí Olúwa. 9“ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò. 10Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu. 11“ ‘Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún Olúwa pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.