Numeri 28:18
Numbers 28:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan.
Numbers 28:18 in English
Numbers 28:18 · Berean Standard Bible
On the first day there is to be a sacred assembly; you must not do any regular work.
Context
16“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé. 17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 18Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19Ẹ rú ẹbọ sísun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù. 20Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.