Numeri 27:3
Numbers 27:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.
Numbers 27:3 in English
Numbers 27:3 · Berean Standard Bible
“Our father died in the wilderness, but he was not among the followers of Korah who gathered together against the LORD. Instead, he died because of his own sin, and he had no sons.
Context
1Ọmọbìnrin Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa. 2Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé, 3“Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀. 4Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.” 5Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.