Native Bible

Numbers 27:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Aaroni arákùnrin rẹ ṣe ṣe,

Numbers 27:13 in English

Numbers 27:13 · Berean Standard Bible

After you have seen it, you too will be gathered to your people, as your brother Aaron was;

Context

11Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ” 12Nígbà náà Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sì orí òkè Abarimu yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. 13Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Aaroni arákùnrin rẹ ṣe ṣe, 14nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.) 15Mose sọ fún Olúwa wí pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.