Native Bible

Numbers 26:47 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400).

Numbers 26:47 in English

Numbers 26:47 · Berean Standard Bible

These were the clans of Asher, and their registration numbered 53,400.

Context

45Ti àwọn ọmọ Beriah: ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi; ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli. 46(Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.) 47Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400). 48Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni; 49ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri; ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.