Native Bible

Numbers 26:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.

Numbers 26:39 in English

Numbers 26:39 · Berean Standard Bible

the Shuphamite clan from Shupham,* and the Huphamite clan from Hupham.

Context

37Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 38Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu; 39ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu. 40Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí: ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi; ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani. 41Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.